Jeremiah 50

Àsọtẹ́lẹ̀ ní ti Babeli

1 aÈyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu wòlíì Jeremiah láti sọ fún ará ilẹ̀ Babeli:

2“Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde,
kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀
ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé,
‘a kó Babeli,
ojú tí Beli,
a fọ́ Merodaki túútúú,
ojú ti àwọn ère rẹ̀,
a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’
3Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò
sì máa gbóguntì wọ́n.
Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò
sá kúrò ní ìlú yìí.

4“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”
ni Olúwa wí,
“Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá,
àwọn, àti àwọn ọmọ Juda,
wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí
Olúwa Ọlọ́run wọn
5Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn
yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a
darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé,
tí a kì yóò gbàgbé.

6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,
àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà,
wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè
wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,
wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.
7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ
àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi
nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé
òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

8“Jáde kúrò ní Babeli,
ẹ fi ilẹ̀ àwọn ará Kaldea sílẹ̀,
kí ẹ sì jẹ́ bí òbúkọ níwájú agbo ẹran.
9Nítorí pé èmi yóò ru,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Babeli àwọn orílẹ̀-èdè
ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀;
Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò
dàbí ọfà àwọn akọni akíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo
10A ó dààmú Babeli, gbogbo
àwọn tó dààmú rẹ yóò sì mú
ìfẹ́ wọn ṣẹ,”
ni Olúwa wí.

11“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,
ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn
fi ayọ̀ fò bí ẹgbọrọ abo màlúù sí koríko tútù,
ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin.
12Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ
yóò sì gba ìtìjú.
Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti aginjù tí kò lọ́ràá.
13Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;
ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.
Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Babeli yóò
fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

14“Dúró sí ààyè rẹ ìwọ Babeli
àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ n ta ọfà náà.
Ẹ ta ọfà náà sí i, nítorí ó ti ṣẹ̀ sí Olúwa.
15Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà!
Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀,
níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san Olúwa,
gbẹ̀san lára rẹ̀.
Ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.
16Ké afúnrúgbìn kúrò ní Babeli,
àti ẹni tí ń di dòjé mú ní igà ìkórè!
Nítorí idà àwọn aninilára
jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀,
kí oníkálùkù sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.

17“Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri,
kìnnìún sì ti lé e lọ.
Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ,
àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli
fa egungun rẹ̀ ya.”
18Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí;

“Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.
19Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli
padà wá pápá oko tútù rẹ̀
òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani,
a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè
Efraimu àti ní Gileadi
20Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”
ni Olúwa wí,
“À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli,
ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun;
àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan
nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.

21“Kọlu ilẹ̀ Merataimu àti àwọn
tí ó ń gbé ní Pekodi.
Lépa rẹ pa, kí o sì parun pátápátá,”
ni Olúwa
“Ṣe gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.
22Ariwo ogun wà ní ilẹ̀ náà
ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìparun ńlá.
23Báwo ni ó ṣe fọ́, tí ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó,
lọ́wọ́ òòlù gbogbo ayé!
Báwo ní Babeli ti di ahoro
ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
24Mo dẹ pàkúté sílẹ̀
fún ọ ìwọ Babeli,
kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀,
o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako Olúwa.
25 Olúwa ti kó àwọn ohun èlò ìjà rẹ̀ jáde,
nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun
ti ṣiṣẹ́ ní ilẹ̀ Babeli.
26Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo,
sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀,
ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà,
Kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun,
ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.
27Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ,
jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n!
Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé,
àkókò ìbẹ̀wò wọn.
28Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá,
sì sọ ní Sioni,
Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san,
ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

29“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli,
ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà.
Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe,
ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga
Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀
yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn
ológun lẹ́nu mọ́,”
Olúwa wí.
31“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“nítorí ọjọ́ rẹ ti dé,
àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.
32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò
sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde.
Èmi yóò tan iná ní ìlú náà,
èyí tí yóò sì jo run.”
33Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ:

“A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli
lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú.
Gbogbo àwọn tí ó kó wọn
nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin
wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà.
34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára,
Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀.
Yóò sì gbe ìjà wọn jà,
kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà;
ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.

35“Idà lórí àwọn Babeli!”
ni Olúwa wí,
“lòdì sí àwọn tó ń gbé ní Babeli,
àwọn aláṣẹ àti àwọn amòye ọkùnrin.
36Idà lórí àwọn wòlíì èké
wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun,
wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.
37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀
àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọn yóò di obìnrin.
Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀!
38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ.
Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère,
àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

39“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù
pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀,
abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀,
a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé,
bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.
40Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba
Sodomu àti Gomorra
pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,”
ni Olúwa wí,
“kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.

41“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá;
orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń
gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé.
42Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,
wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.
Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ.
Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.
43Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,
ọwọ́ wọn sì rọ,
ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.
44Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani
sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

45Nítorí náà, gbọ́ ohun tí
Olúwa sọ nípa Babeli
ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì
sí Babeli; n ó sì pa
agbo ẹran wọn run.
46Ní ohùn igbe ńlá pé;
a kò Babeli, ilẹ̀ ayé yóò mì tìtì,
a sì gbọ́ igbe náà
láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Jeremiah 51

1Ohùn ti Olúwa wí nìyìí:

“Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè
sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai
2Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli
láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo;
wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà
ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.
3Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀
jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀;
má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
sí, pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.
4Gbogbo wọn ni yóò ṣubú
ní Babeli tí wọn yóò sì
fi ara pa yánnayànna ní òpópónà.
5Nítorí pé Juda àti Israẹli ni
Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn
kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.

6 b“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà
fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
Àsìkò àti gbẹ̀san Ọlọ́run ni èyí,
yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́.
7 cIfe wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa;
ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí.
Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀,
wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.
8Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́;
Ẹ hu fun un!
Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ,
bóyá yóò le wo ọ́ sàn.

9“ ‘À bá ti wo Babeli sàn,
ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀,
kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè,
ó ga àní títí dé òfúrufú.’

10“ ‘Olúwa ti dá wa láre,
wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa
Ọlọ́run wa ti ṣe.’

11“Ṣe ọfà rẹ ní mímú,
mú apata!
Olúwa ti ru ọba Media sókè,
nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run.
Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
12Gbé àsíá sókè sí odi Babeli!
Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí,
ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri,
ẹ ṣètò àwọn tí yóò sápamọ́
Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde,
òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.
13 dÌwọ tí o gbé lẹ́bàá odò púpọ̀,
tí o sì ni ọ̀rọ̀ púpọ̀; ìgbẹ̀yìn rẹ ti dé,
àní àsìkò láti ké ọ kúrò!
14 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra fún ara rẹ̀,
Èmi yóò fún ọ ní ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ eṣú,
wọn yóò yọ ayọ̀, ìṣẹ́gun lórí rẹ.

15“Ó dá ilẹ̀ nípa agbára rẹ̀,
o dá ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,
o sì tẹ́ ọ̀run pẹ̀lú ìmọ̀ rẹ̀.
16Nígbà tí ará omi ọ̀run hó
ó mú kí òfúrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé.
Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.

17“Olúkúlùkù ènìyàn ni kò lọ́pọlọ
tí kò sì ní ìmọ̀, olúkúlùkù
alágbẹ̀dẹ ni a kó ìtìjú bá nípa òrìṣà rẹ̀.
Àwọn ère rẹ jẹ́ ẹ̀tàn wọn kò ní èémí nínú.
18Asán ni wọ́n, àti iṣẹ́ ìsìnà,
nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn ó ṣègbé.
19Ẹni tí ó jẹ́ ìpín Jakọbu kó rí bí ìwọ̀nyí;
nítorí òun ni ó dá ohun gbogbo,
àti gbogbo àwọn ẹ̀yà ajogún,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

20“Ìwọ ni kùmọ̀ ogun ohun èlò ogun mi,
ohun èlò ìjà mi, pẹ̀lú rẹ èmi ó fọ́ orílẹ̀-èdè túútúú,
èmi ó bà àwọn ilé ọba jẹ́.
21Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;
èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú
èmi ó pa awakọ̀
22Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,
pẹ̀lú rẹ, mo pa
àgbàlagbà àti ọmọdé,
Pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin.
23Èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ olùṣọ́-àgùntàn,
àti agbo àgùntàn rẹ̀ túútúú,
èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àjàgà màlúù túútúú,
èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ túútúú.
24“Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Babeli àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Sioni,”

ni Olúwa wí.
25“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun
ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,”
ni Olúwa wí.
“Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ,
èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta,
Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.
26A kò ní mú òkúta kankan láti
ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí
fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di
ahoro títí ayé,”
Olúwa wí.

27“Gbé àsíá sókè ní ilẹ̀ náà!
Fọn ìpè láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
Sọ àwọn orílẹ̀-èdè di mímọ́ sórí rẹ̀,
pe àwọn ìjọba yìí láti dojúkọ ọ́:
Ararati, Minini àti Aṣkenasi.
Yan olùdarí ogun láti kọlù ú,
rán àwọn ẹṣin sí i bí ọ̀pọ̀ eṣú.
28Sọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ọba Media di mímọ́ sórí rẹ̀,
àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀,
àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ ọba lé lórí.
29Ilẹ̀ wárìrì síhìn-ín sọ́hùn-ún, nítorí pé
ète Olúwa, sí Babeli dúró
láti ba ilẹ̀ Babeli jẹ́ lọ́nà
tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.
30Gbogbo àwọn jagunjagun
Babeli tó dáwọ́ ìjà dúró sínú àgọ́ wọn.
Agbára wọn ti tán, wọ́n ti dàbí obìnrin.
Ibùgbé rẹ̀ ni a ti dáná sun,
gbogbo irin ẹnu-ọ̀nà wọn ti di fífọ́.
31Ìránṣẹ́ kan ń tẹ̀lé òmíràn
láti sọ fún ọba Babeli pé
gbogbo ìlú rẹ̀ ni a ti kó ní ìgbèkùn.
32Odò tí ó sàn kọjá kò sàn mọ́
ilẹ̀ àbàtà gbiná, àwọn jagunjagun sì wárìrì.”
33Ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli sọ nìyìí:

“Ọmọbìnrin Babeli dàbí ìpakà àsìkò láti kórè rẹ̀ kò ní pẹ́ dé mọ́.”

34“Nebukadnessari ọba Babeli tó jẹ wá run,
ó ti mú kí ìdààmú bá wa,
ó ti sọ wá di àgbá òfìfo.
Gẹ́gẹ́ bí ejò, ó ti gbé wa mì.
Ó fi oúnjẹ àdídùn wa kún inú rẹ̀,
lẹ́yìn náà ni ó pọ̀ wá jáde.
35Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,”
èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí.
“Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,”
ni Jerusalẹmu wí.
36Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí:

“Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí
ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san,
èmi yóò mú kí omi Òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.
37Babeli yóò parun pátápátá,
yóò sì di ihò àwọn akátá,
ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.
38Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù
bí ọmọ kìnnìún.
39Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè,
èmi yóò ṣe àsè fún wọn,
èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó
tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín,
lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,”
ni Olúwa wí.
40“Èmi yóò fà wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn
tí a fẹ́ pa, gẹ́gẹ́ bí àgbò àti ewúrẹ́.

41“Báwo ni Ṣeṣaki yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé.
Irú ìpayà wo ni yóò bá
Babeli láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
42Òkun yóò ru borí Babeli,
gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Babeli.
43Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro,
ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn
kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.
44Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli
àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì.
Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́.
Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó.

45“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀
ẹ̀yin ènìyàn mi!
Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!
Sá fún ìbínú ńlá Ọlọ́run.
46Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú
tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí
a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;
àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,
òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá
ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.
47Nítorí ìgbà náà yóò wá
dandan nígbà tí èmi
yóò fi ìyà jẹ àwọn
òrìṣà Babeli, gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì
gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.
48Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,
yóò sì kọrin lórí Babeli:
nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”
ni Olúwa wí.

49“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli,
gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.
50Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró:
Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè,
ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”

51“Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn:
ìtìjú ti bò wá lójú
nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

52“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀:
àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀
53Bí Babeli tilẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,
bí ó sì ṣe ìlú olódi ní òkè agbára rẹ,
síbẹ̀ àwọn afiniṣèjẹ yóò ti ọ̀dọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá,”
Olúwa wí.

54“Ìró igbe láti Babeli,
àti ìparun láti ilẹ̀ àwọn ará Kaldea!
55Nítorí pé Olúwa ti ṣe Babeli ní ìjẹ,
ó sì ti pa ohun ńlá run kúrò nínú rẹ̀;
àwọn ọ̀tá wọn sì ń hó bi omi púpọ̀, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.
56Nítorí pé afiniṣèjẹ dé sórí rẹ̀,
àní sórí Babeli;
a mú àwọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn:
nítorí Ọlọ́run ẹ̀san ni Olúwa,
yóò san án nítòótọ́.
57Èmi ó sì mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ yó bí ọ̀mùtí,
àti àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀
àti àwọn baálẹ̀ rẹ̀, àti àwọn akọni rẹ̀,
wọn ó sì sun oorun láéláé, wọn kì ó sì jí mọ́,”
ní ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
58Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Odi Babeli gbígbòòrò ní a ó wó lulẹ̀ pátápátá,
ẹnu-bodè gíga rẹ̀ ní a ó sì fi iná sun:
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ṣiṣẹ́ lásán,
àti àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣiṣẹ́ fún iná,
tí àárẹ̀ sì mú wọn.”
59Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó. 60Jeremiah sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ ibi tí yóò wá sórí Babeli sínú ìwé kan, àní gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a kọ sí Babeli. 61Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 62Kí ìwọ kí ó sì wí pé, ‘Olúwa ìwọ ti sọ̀rọ̀ sí ibí yí, láti ké e kúrò, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀, àti ènìyàn àti ẹran, nítorí pé yóò di ahoro láéláé.’ 63 eYóò sì ṣe, nígbà tí ìwọ bá parí kíka ìwé yìí tán kí ìwọ kí ó di òkúta mọ́ ọn, kí ó sì sọ ọ́ sí àárín odò Eufurate. 64Kí ìwọ sì wí pé, ‘Báyìí ní Babeli yóò rì, kí yóò sì tún dìde kúrò nínú ibi tí èmi ó mú wá sórí rẹ̀: àárẹ̀ yóò sì mú wọn.’ ”

Títí dé ìhín ni ọ̀rọ̀ Jeremiah.

Copyright information for YorBMYO